Yoruba

Ilé ìfowópamọ́ ìdàgbàsókè ilẹ̀ adúláwọ̀ késíjọba láti mọ́rọ̀ ìdàgbàsókè ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn lọ́kunkúndùn

Ilé ìfowópamọ́ tón r;is;i ìdàgbàsókè ilẹ̀ adúláwọ̀, AFDB, àti àjọ tón rí sétò ìsúná ìdàgbàsókè ẹ̀ka ètò ọ̀gbìn nílẹ̀ òkèrè, IFAD, ti mú ìpínlẹ̀ Ògùn gẹ́gẹ́ bí ibití àkànse ètò ọ̀gbìn kan tíwọ́n sàgbékalẹ̀ yóò ti wáyé.

Olùdarí àjọ IFAD, nílẹ̀ yíì, ọ̀mọ̀wé Patrick Habamenshi ló sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀, lákokò tí ikọ̀ rẹ̀ àti ti ilé ìfowópámọ́ tón rísí ìdàgbàsókè ilẹ̀ adúláwọ̀ sàbẹ̀wò ẹnusẹ́ sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, ọmọba Dapọ Abiọdun lágbègbè òkè Mosan nílu Abẹokuta.

Ọmọwe Patrick sọpé àwọn ànfàní tópọ̀ ló sodo sẹ́ka ètò ọ̀gbìn èyí tó lé mú ìlọsíwájú bá, ìdí, sini yi tó fi sepàtàkì fún ìjọba láti dókoowò sẹ́ka ọ̀hún.

Nígbà tó ń báwọn ikọ̀ náà sọ̀rọ̀, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, ọmọọba Dapọ Abiọdun sàlàyé pé, inú òun dùn gidigidi bíwọ́n se mú ìpínlẹ̀ Ògùn láàrin àwọn ìpínlẹ̀ tón bẹ lórílẹ̀dè yíì láti jànfàní látara tíwọ́n fẹ́ bgékalẹ̀ náà pẹ̀lú àtọ́kasí pé, isẹ́ àkànse ọ́hún ló wà níbamu pẹ̀lú èróngbà ìsèjọba òun lẹ́ka ètò ọrọ̀ ajẹ́.

Aminat/Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *