Yoruba

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn fọwọ́sí gbigba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ B.Tech nílé ẹ̀kọ́ gbogbonìse Moshood Abiọla

Gẹ́gẹ́ bí ara áyan láti mú àgbéga bá ìmọ̀ ẹ̀rọ àtètò isẹ́ ọwọ́ lórílẹ̀dè yíì ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn ti fọwọ́sí gbígba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ, B.Tech nílé ẹ̀kọ́ gbogbonìse Poly Moshood Abiọla tó wà nílu Abẹokuta, Mapoly.

Gómìnà ìpínlẹ̀ náà, ọmọba Dapọ Abiọdun sọ nínú ìwé tó kọ ránsẹ́ sí alákoso fétò ẹ̀kọ́, ìmọ̀ sayẹnsi àtìmọ̀ ẹ̀rọ nípinlẹ̀ náà, ọ̀jọ̀gbọ́n Abayọmi Arigbabu fún fífọwọ́sí gbigba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ọ̀hún nílé ẹ̀kọ́ gbogbonìse poly ọ̀hún, gbọdọ tete bere ètò rẹ̀ pẹ̀lú ilé-ẹ̀kọ́ gíga fasiti Ọlabisi Ọnabanjọ, láti fi lánfani sí ìkẹ́kọ́ọ̀ gboyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ nílé ẹ̀kọ́ gbogbonìse Mapoly.

Gómìnà kò sài sàlàyé pé, fífọwọ́sí ètò náà ni yóò wà níbamu pẹ̀lú ìlànà tájọ tón rí sọ́rọ̀ àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga fasiti akẹkọọ gbnoye ìmọ̀ ìjìnlẹ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ, adelé ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ gbogbnìse Mapoly, ọ̀gbẹ́ni Adeoye Odedeji sàlàyé pé, ètò ìkẹ́kọ́ọ̀ náà làfojúsùn rẹ̀ yóò jẹ́ kíkọ́ ètò nípa isẹ́ ọwọ́ àti tìmọ̀ ẹ̀rọ.

Fọlarin/Wojuade

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *