Gomina Ipinle Oyo, Onimo Ero Seyi Makinde ti so di mimo pe ijoba re yoo se asepo pelu ajo to n ri si idagbasoke oja kiko sowo soke okun , NEPC, lona ati sogba pelu awujo agbaye nidi oja kiko sowo sile okeere.

Gomina se asoyan oro yi lasiko abewo si oludari ajo naa, Oloye Olusegun Awolowo se sodo re nilu Ibadan.

Gomina eni to akowe ijoba ipinle Oyo Arabinrin Olubamiwo Adeosun soiju fun tenumo pe Ijoba Ipinle Oyo ti mu agbega ba ise agbe di aladanla nilana igbalode.

Gomina  salaye wi pe ijoba re ti se atunse opolopo ona lagbegbe igberiko lona ati mu igbe aye rorun fawon agbe.

Ninu oro re, oludari agba ajo ton ri si ipolongo oja kiko sowo sile okeere , NEPC, oloye olusegun awolowo pe fun ajosepo to dan moran pelu ajo naa fun ipese ise.

Oloye Awolowo tenumo pe ajo naa yoo se ise po pelu Ijoba Ipinle Oyo lati fi mu igba otun ba Oja Okerete to wa nilu Saki tii se enu aala ile yi fun anfaani awon eeyan Ipinle Oyo.

Adebisi/Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *