Ijoba ipinle Ekiti sope, oun ti ko abala keji abere ajesara to n dena arun Covid-19 bi egberun lona ogoji de sipinle naa latije to n ri soro idagbasoke ibudo eto ilera alabode nile yi.
Alakoso feto ilera atoro omoniyan, Dokita Oyebanji Filani to siso loju oro naa nilu Ado–Ekiti salaye pe, igbese naa yoo jeki ipinle Ekiti tesiwaju lati maa fawon eeyan ipinle labere ajasara ohun lati dena itankale arun covid-19.
Dokita Filani tun sope, abala akoko abere ajesara ohun tiwon gbe wa fun ipinle naa lawon samulore dada.
Ko sai tenumo pe, isejoba to naa lode bayi ti pinnu lati pese eto ilera to ye kaaro faraalu, pelu afikun pe, ko si olugbe kan tiwon yoo fissile laigba bere ajesara to n dena arun Covid-19 nipinle Ekiti.
Folakemi Wojuade/Omolola Alamu


