Yoruba

Ilé isẹ́ ọmọ ogun ojú òfurufú bèèrè fún àtìlẹyì aráàlu lórí gbígbógun ti ètò àbò tó mẹ́hẹ.

Ilé isẹ́ ọmọ ogun ojú òfurufú ilẹ̀ yíì, NAF, ti rọ àwọn èèyàn láti máà sàtìtilẹyìn fákitiyan àwọn òsìsẹ́ aláàbo gbogbo, kópin lè dé bá àbò tó mẹ́hẹ yíká ilẹ̀ Nàijírìa.

Ọga ọmọ ogun ojú òfurufú , Sunday Makinde ló pàrọwà yíì lẹ́yìn ètò ìsìn alájùmọ̀se kan towa ye láti fi sàmì ayẹyẹ ọdún kẹtàdínlọ́gọ́ta ilé-isẹ́ ọmọ ogun ojú òfurufú ọ̀hún.

Gẹ́gẹ́ bọgagun ojú òfurufú náà sewípé, àtìlẹyìn aráàlu nìkan lọ́nà kan gbogi láti sàseyọ́rí lórí ìgbésẹ̀ gbígbógun ti ìwà ìgbésùnmọ̀mí àtọ̀rọ̀ àilétò àbò tó gogò láwọn apá ibíkan nílẹ̀ yíì, èyí tón lọ́wọ́.

Kò sài fọwọ́ ìdánilójú sọ̀yà pé, ilé-isẹ́ ọmọ ogun ojú òfurufú náà lábẹ́ olùdarí ọ̀gágun Isiaka Amọo yóò tẹ̀síwájú láti pèsè ètò àbò tó wa níkapá rẹ̀ látorí òfurufú nígbogbo ẹkùn tónbẹ nílẹ̀ yíì, láti lè sàseyọ́rí lórí ìgbésẹ̀ náà.

Ọgagun Makinde wá tẹnumọ́ ìpinnu rẹ̀ láti sisẹ́ lórí ọ̀nà tabo àti ìsọ̀kan ilẹ̀ Nàijírìa yóò fi rẹ́sẹ̀ walẹ̀.

Biyi Fadahunsi/ Folakemi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *