Àjọ elétò ìdìbò nílẹ̀ yíì, INEC, sọ pé, òun ti ń sisẹ́ lórí báwọn yóò se gùnlé ètò ìforúkọsílẹ̀ olùdìbò padà, bẹ̀rẹ̀ lọ́tọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n osù, kẹfà ọdún yíì.

Alákoso àjọ elétò ìdìbò tí tún se alága ìgbìmọ̀ fétò ìròyìn àti ìlanilọ́yẹ̀ olùdìbò, ọ̀gbẹ́ni Festus Okoye ló sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ fáwọn oníròyìn nílu Abuja.

Ọgbẹni Okoye sàlàyé pé, gbogbo ètò loti tó lórí ìbẹ̀rẹ̀ ètò ìforúkọsílẹ̀ olùdìbò náà tí yóò máà tẹ̀síwájú lósù tónbọ̀.

Kò sài tún mẹ́nu bàwọn ìgbésẹ̀ tó se kókó tóníse pẹ̀lú ìbẹrẹ ètò iforikọsilẹ ọ̀hún, nínú ètò ìdìbò wa lárọwọ́tó aráàlu, sísàyẹ̀wò ètò ìforúkọsílẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára, àti sísètò ìdánilẹ́kọ fáwọn òsìsẹ́ ti yóò máà ribétò ìforúkọsílẹ̀ náà látorí ẹ̀rọ ayélujára.

A ó ránti pé, sáájú lalága àjọ elétò ìdìbò náà, INEC, ti kéde pé, ètò ìforúkọsílẹ̀ olùdìbò náà yóò tẹ̀síwájú títí di abala kẹta ọdún 2022.

Biyi Fadahunsi/ Folakemi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *