News Yoruba

Ọgagba Ilésẹ́ Ọlọ́pa Sèkìlọ̀ Lórí Dídá Rògbòdìyàn Sílẹ̀ Sáàjú Àyájọ́ June 12

Báyajọ́ ọjọ́ òmìnira, June 12 sen kànkù, ọ̀gágba ilésẹ́ ọlọ́pa ọ̀gbẹ́ni Usman Baba ti pa lásẹ, pé, kí gbogbo igbákejì olùdarí ilésẹ́ ọlọ́pa tó fimọ́ àwọn alámojútó nípinlẹ̀ kọ̀kan, àti olúlu ilẹ̀ yí, láti fi ìyà tótọ́ jẹ ẹnikẹ́ni àti ẹgbẹ́ tó bá fẹ́ lo ọjọ́ náà láti dúnkokò mọ́ àláfìa nílẹ̀ yí.

Nígbà tón sọ̀rọ̀ níbi ìpàdè pẹ̀lú àwọn lọ́galọ́ga nílesẹ́ ọlọ́pa nílu Abuja, ló ti sọ̀rọ̀ yí, tó sì rọ̀ wọ́n láti sisẹ́ wọn bi isẹ́, lái bgójú àgan sí àwọn èyàn ilẹ̀ yí tí wọ́n tẹ̀lé òfin àti òlànà láyajọ́ ọjọ́ àwarawa.

Ọgagba ilésẹ́ ọlọ́pa, sọ pé, isẹ́ ńlọ láti fẹsẹ̀ àbò múlẹ̀, lásìkò àyájọ́ yi àti lẹ́yìn rẹ̀.

Ọgbẹni Baba wá koròju sí báwọn ilésẹ́ ọlọ́pa miran seń gbẹsẹ lé ọkọ̀ láini ìdígidi kan ní pàtó, pẹ̀lú àtọ́kasí pé irúfẹ́ àwọn ọkọ̀ yi ni kí wọ́n dá padà fáwọn tóòní, nítorípé ósese kó fa ìkọlù ilésẹ́ ọlọ́pa.

Net /Afọnja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *