News Yoruba

Àwọn Aya Gómìnà Ké Gbàjerè Lórí Ètò Àbò Tó Mẹ́hẹ

Àwọn aya Gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ aya Gómìnà nílẹ̀ Nàijírìa ti bu ẹnu àtẹ́lu bí ètò àbò seń mẹ́hẹ yíká ilẹ̀ yí.

Bákanà ni wọ́n fi àidúnú hàn lórí bí isẹ́ òn òsì seń gogò si, àinísẹ́ lọ́wọ́ àwọn èyàn nílẹ̀ yí tófimọ́ àwọn ìwà ìbàjẹ́ miràn.

Alága ẹgbẹ́ náà, Arábìnrin Bisi Fayẹmi títúnse aya Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì ló sọ̀rọ̀ yí lásìkò tón bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé kan nílu Abuja.

Àwọn aya Gómìnà wá sọ pé àwọn ti setán láti sisk pẹ̀lú ọkọ wọn nípinlẹ̀ kóowá wọn, láti sisẹ́ ri dájú pé ètò àbò rẹsẹ̀ walẹ̀ nípinlẹ̀ ọ̀kọ̀kan wọn.

Gẹ́gẹ́bí arábìnrin Fayẹmi tiwí, ẹgbẹ́ ọ̀hún kọminú lórí ipa tí ètò àbò yo ni lórí àwọn obìnrin àti ọmọdé lápapọ̀.

Ó wá tẹnuma pé, ẹgbẹ́ náà yo tlsíwájú láti ma sàtìlẹ́yìn fún ètò ìsèjọba nípinlẹ̀ kówa’wọn, kámugbòrò lè débà ìgbéayé àwọn arálu yíká ilẹ̀ yí.

Fadahunsi /Afọnja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *