Ijoba ipinle Oyo ti funle igbese kiko awon alagbe kuro nibi ti won pejo si lopopona Jenbewon, lagbegbe Sabo nilu Ibadan lo si aaye tuntun ti won pese fun won lagbegbe Akinyele.
Igbese naa ti won bere lait bii osu melo kan seyin ni won side re ni sansan laaro oni, leyin ti awon asaaju awujo Arewa ati asoju awon alagbe naa ti se abewo si ibudo tuntun naa lojo abameta ko koja yi.
Alabojuto oro ayika, Amofin Idowu Oyeleke, eni ti saaju ibi akoko awon alagbe naa lo si Akinyele salaye wipe opo nnkan amayederun ni won pese si ibudo naa ti, ileewe, ilee iwosan ati aaye igbafe.
Atejade ti akowe iroyin fun Gomina Seyi Makinde,iyen Ogbeni Taiwo Adisa fi sita deke awon ileese, oioba ti lowo ninu igbese naa bii ileese ti nri soro awon obinrin ati irin ajo afe, ileese oro ijoba ibile ati oye jije to fi mo ofiise akowe ijoba ipinle Oyo pelu ajo eleto aabo, eyi ti alamojuto ileese olopa nigba kan ri Ogbeni Fatai Owoseni je olori fun.
Ekun oko elero ijoba nla taa mo si pacesetters bus meta lo ti ko awon alagbe naa lati opoppona Jenbewon lo si agbegbe Akinyele ti awon mii si tun n ko won lowo.
Kehinde/Saludeen


