News Yoruba

Ilésẹ́ ọlọ́pa sísọ lójú àwọn tí wọ́n furasí lórí rògbòdìyàn tó wáyé láipẹ yi lágbègbè Ìwó Road.

Alábojútó ilésẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ arábìnrin Ngozi Onadeko ti sísọ lótú àwọn ẹni tí wọ́n furasí mẹ́ta tí wọ́n ni ǹkánse pẹ̀lú rògbòdìyàn tó wáyé lọ́sẹ̀ tó kọjá ládugbò Ìwó Road ìbàdàn.

Nígbà tón sísọ, lójú àwọn ẹni wọ̀yí arábìnrin Onadeko sọpé kété tí rògbòdìyàn ọ̀hún wáyé lárin alábojútó ibùdókọ̀ àti ẹnìkan tó ní yàrá ìtàjà ìgbàlódé ládugbò ìwó road làwọn ọlọ́pa ti bẹ̀rẹ̀ ìwádi tó yọrísí bọ́wọ́ se tẹ àwọn ẹni tí wọ́n furasí mẹ́tàta.

Tó sì ní isẹ́ sinlọ lọ́wọ́ lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà, láti jẹ́ kọ́wọ́ sìnkú agbófinró tẹ àwọn kọ́lọ́rànsí ẹ̀dá tó ti sálọ, àti wípé ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ yo di àfọ̀mọ́ kúrò lọ́wọ́ ètò àbò.

Alábojútó ilésẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ wá bèrè fún atilẹyin látọ̀dọ̀ àwọn èyàn àwùjọ, nípa fífi tó wọn létí on tón sẹlẹ̀ lágbègbè wọn.

Arábìnrin Onadeko fikun pé àwọn tí wọ́n furasí yi ni wọ́n yo mójú wọn balé ẹjọ́ láipẹ lẹ́yìn ti ìwádi bá parí.

Makinde/Afọnja

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *