Ìjọba ìpínlẹ̀ Òndó ti sèkìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn láti sọ ewé agbéjẹ́ mọ́wọ́ ní gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ méjìdínlógún tó wà nípinlẹ̀ ọ̀hún lẹ́yẹ ọ̀sakà.

Alábojútó lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn àti títa arálu jí sójúse ẹni, ọ̀gbẹ́ni Donald Ojogo ló sọ̀rọ̀ yí fún àwọn akọ̀ròyìn tó sì sọ pé ìpinu yi ni wọ́n fẹnukò lé lórí lẹ́yìn ìpàdé ìgbìmọ̀ alásẹ nípinlẹ̀ náà.

Ọgbẹni Ojogo tón gba àwọn òbí atálàgbátọ níyànjú láti túnbọ̀ kíyèsí àwọn ọmọ sọ pé òfin tó de wíwa alùpùpù lẹ́yìn ago mẹ́fa ìrọ̀lẹ́ ló si fẹsẹ̀ múlẹ̀.

Pẹ̀lú àtọ́kasí pé ìgbésẹ́ náà lówà níbamu lórí kí àbò tó múnádoko lówà fún ẹ̀mí àti dúkia, bákanà ló sọ pé yó mu kí ìwà ọ̀daràn dínkù jọjọ nípinlẹ̀ Òndó.

Alábojútó ọ̀hún, fikun pé, ìfofinde yi ló padandan pẹ̀lú báwọn kọ̀lọ̀rànsí ẹ̀dá sén fi alúpúpú bójú hùwà ọ̀daràn láwùjọ.

Ololade Afonja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *