Yoruba

Ati wọlé sílé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ nọ́ọ̀si: Iléesẹ́ olóògun òfurufú sèkìlọ̀ fáràlú nítorí àwọn oníjìbìtì

Iléèsẹ́ olóogun ofurufu ilẹ̀ yí ti sèkìlọ̀ fáwọn ọmọ orílẹ̀èdè yí tó n lépa àti wọlé sílé ẹ̀kọ́ gíga ìmọ̀ nọ́ọ̀si pé kí wọ́n sọ́ra kí wọn ma báà bọ́ sọ́wọ́ àwọn oníjìbìtì.

Ìkìlọ̀ yí ló wáyé nípa ayédèrú ìwé ìgbaniwọlé sílé ẹ̀kọ́ náà tó ń lọ káàkiri orí ẹ̀rọ ayélujára.

Olùdarí ètò ìròyìn ọ̀hún kéde olú iléésẹ́ oloogun ofurufu ilẹ̀ yí, Air Comadar Edward Gabkwet ló sọ ọ̀rọ̀ yí di mímọ̀ nínú àtljáde tó fi síta nílu Abuja.

Gẹ́gẹ́ bí Air Commander Gabkwet se wí, ẹni tó wà nidi ayédèrú ìwé ìgbaniwọlé sílé ẹ̀kọ́ nọ́ọ̀si tó jẹ́ tiléésẹ́ ologun ló sọ̀rọ̀ di mímọ̀ fún àwọn tó fẹ́ lù ní jìbìtì pé kí wọ́n san ẹgbẹ̀rún mẹẹdogun àti ẹẹdẹgbẹta naira sí ọfììsì akọ̀wé àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà.

Ó wá sàlàyé ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ wípé bí wọ́n se ń laago ìkìlọ̀ náà tó ọ̀pọ̀ aráalu ló tún ń bọ̀ sọwọ àwọn oníjìbìtì ẹ̀dá yi.

Ó wá sọ abẹdaju pé, ileesẹ oloogun ofurufu ilẹ̀ yí ríì dájú pé wọ́n fi kéde fún gbé oníjìbìtì náà pẹ̀lú gbogbo àwọn abẹsinkawọ rẹ, tí wọ́n yóò si fara gbegba òfin.

Babatunde Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *