Yoruba

Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ ìsẹ́gun àti ọjọ́rú tónbọ̀ gẹ́gẹ́bí ìsimi lẹ́nu isẹ́ láti sọdún iléyá

Ìjọba àpapọ̀ ti kéde ọjọ́ ìsẹ́gun Tuesday àti ọjọ́rú Wednesday ọ̀sẹ̀ tónbọ̀ gẹ́gẹ́bí ìsinmi lẹ́nu isẹ́ láti le sọdún iléyá tọdún yi.

Ọrọ yí lówà nínú àtẹ̀jáde èyí tí àkọ̀wé àgbà sí alákoso lórí ọ̀rọ̀ abẹ́lé, ọ̀mọ̀wé Shuaib Belgore fisíta, pẹ̀lú àtọ́kasí pé alákoso fọ́rọ̀ abẹ́lé Rauf Arẹgbẹsọla ló kéde ohun, lórúkọ ìjọba àpapọ̀ nílu Abuja.

Ọgbẹni Arẹgbẹsọla wá, kí gbogbo àwọn Mùsùlùmí òdodo àti àwọn èyàn nílẹ̀ Nàijírìa, nílé àti lókè òkun kú ọdún Eil-el-kabir.

Alákoso wá rọ gbogbo àwọn èyàn nílẹ̀ yí láti tẹ̀lé gbogbo ìlànà tó rọ̀mọ́ dídènà ìtànkákẹ̀ àrùn covid-19 papa wiwọ ibomu, fífọ ọwọ́ lórekére àti yíyàgò fún ìfin kínra.

Ololade Afọnja  

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *