Yoruba

Ọgagun àgbà nilẹ̀ yí Yahaya gbósùbà fáwọn ikọ̀ tó ń kojú àwọn agbésùnmọ̀mì fún isẹ́ akọni wọn.

Ọgagun àgbà lórílẹ̀èdè yí, ọ̀gágun Faruk Yahaya ti rọ àwọn ológun ọ̀wọ́ kẹjọ iléèsẹ́ ológun ilẹ̀ yí pẹ̀lú àwọn ikọ̀ tí wọ́n pe ní Hadarin Daji pé kí wọ́n tẹpẹlẹ mọ́ igbokegbodo wọn nídi ogun gbigbe ti àwọn ukẹ agbesunmọmi.

Eyi ló jẹyọ nínú àtẹ̀jáde tí olùdarí ẹ̀ka ètò ìkede fún iléèsẹ́ ológun ọ̀gágun Onyeme Nwachukwu fi síta nílu Gusan ìpínlẹ̀ Zamfara.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde náà se wí, ọ̀gágun Yahaya pàrọwà yí lásìkò tó ń bá àwọn ikọ̀ ológun náà sọ̀rọ̀.

Ó gbósùbà fún wọn lórí ìgbòkègbodo wọn nídi àti wagbo dẹ́kun fáwọn ọ̀daràn, kí ohun gbogbo ó léè tètè padà po sípò láwọn ìpínlẹ̀ tọ́rọ kan.

Babatunde Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *