News Yoruba

Alakoso Keji Feto Idaleese Sile Tenumo Atileyin Fawon Akanda Eda

Alakoso keji feto idaleese sile, eto okoowo ati oro aje lorileede yi Ambassador, Marian Katagum ti tenumo igbiyanju isejoba Aare Buhari lori atileyin sise fawon akanda eda lorileede yi.

Arabinrin Katagum siso loju oro yi lasiko to n gbalejo asoju egbe awon obinrin to je akanda eda, eyiti akowe egbe naa nile yi Mary Musa saaju mu.

Alakoso na salaye wipe ijoba to wa loke yi ko fowo yepere mu ofo awon akanda eda, leyi to mu ki won se idasile ajo kan ti yoo maa ri si igbaye gbadun won.

O soo di mimo pe, eredi ajo na ni lati le maa wa ojutu si ipenija yoowu ti won ba a koju nipase, eto ati liana tijoba nse.

Saaju ni akowe egbe naa, to tun je asaaju ile to se abewo wi pe won gunle abewo naa fun ajosepo pelu ileese to n ri si idase sile ati eto okoowo loro ati le maa koo awon akanda eda ni ise owo ati gbigba si ise laaye to ba si sile pelu awon anfani mii.

Babatunde Salaudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *