Ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti sèlérí láti pín àwọn àpò ẹ̀fọn tó n gbà látọ̀dọ̀ àjọ ilẹ̀ Amẹrica tón rí ìdàgbàsókè àgbáyé.

Gómìnà Seyi Makinde ẹnití igbákejì olórí òsìsẹ́ fún Gómìnà, ọ̀gbẹ́ni Abdulmojeed Mogbọnjubọla ló jẹ́jẹ yíì lákokò tón tẹ́wọ́gba milliọnu márun àwọn àpò ẹ̀fọn látọ̀dọ̀ àjọ shún.

Gómìnà tọ́kasi pé, ọ̀kan nínú èròngbà ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ni láti sàgbékalẹ̀ àwọn ǹkan mọ́nigbàgbé níbámu pẹ̀lú ríridájú pé, ètò ìlera tó yè kóòro wà fún gbogbo ènìyàn lápapọ̀.

Olùbádámọ̀ràn pàtàkì fún Gómìnà lórí ọ̀rọ̀ ìlera, Dókítà Funmi Salami, sàlàyé pé, orílẹ̀dè Nàijírìa náà kó ìdá kan nínú ikú táwọn èèyàn ńkú látara àisàn ibà yíká agbègbè, ìdí sìnìyí tó fi se pàtàkì fún gbogbo èèyàn láti máà ta àpò ẹ̀fọn sórí ibùsùn wọn tíwọ́n bá ti fẹ́sùn.

Oníròyìn ilé-isẹ́ wa jábọ̀ pé, gbogbo àwọn tọ́rọ̀ kan lẹ́ka ètò ìlera ló péjúpésẹ̀ síbi tájọ náà ti ń gbé àwọn àpò ẹ̀fọn ọ̀hún lé ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ lọ́wọ́, tófimọ́ àwọn olórí ẹ̀sìn.

Kehinde/Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *