Afikun aba isuna oni billionu lona aadota naira ni won ti ka fun Igbakeji nile Igbimo Asofin Ipinle Oyo.

Eyi lo waye leyin ti Gomina Seyi Makinde ti fiwe sowo sile igbimo asofin naa ti adari ile, OgbeniAdebo Ogundoyin si kaa to wa beere fun ijiroro ati ibuwolu re.

Gegebi Gomina Makinde se so, afikun billion lona aadota naira naa lo wa fun awon ise akanse to ko si ninu aba isuna odun 2021.

Awon ise akanse naa ni ona olobiripo ti yio gba billionu lona meedogbon Naira, opopona Iseyin si Ogbomoso ti yio gba billion meedogun naira nigbeti atunse papako ofurufu tilu Ibadan yio gba billionu mewa naira.

Adari ile, Ogbeni Ogundoyin wa sagbekale igbimo kan lori oro isuna lati bojuwo ibeere afikun aba isuna ti Gomina gbe wa naa.

Saaju ni ile igbimo asofin ti buwolu afiku owoya bilionu mefa fun ijoba to Gomina Seyi Makinde nle waju re.

Mospe Kehinde/Oluwayemisi Owonikoko

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *