Lẹ́yìn ẹ̀sùn gbígba ilẹ̀ àtàwọn ilé lágbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Akinyẹle tí wọ́n fi kan ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti késí ọ̀gágba wọnlẹ̀wọnlẹ̀ tótúnjẹ́ akọ̀wé àgbà, nílesẹ́ tón rísí ilẹ̀ àti ìdàgbàsókè àwùjọ nípinlẹ̀ yí.

Nínú àbá èyí tí ọ̀gbẹ́ni Taofeek Kẹhinde tón sojú ẹkùn Akinyẹle kejì, àwọn olùgbé Olosaoko, Alabata, Ajibade, Agbẹdo tófimọ́ abúlé Alase, ló ké gbàjarè lórí bí àwọn àjèjì kan, tó pe rawọn lósìsẹ́ ìjọba se ń lọ kakiri, tí wọ́n sìn wọn ilé lágbègbè wọn.

Ọgbẹni Kẹhinde sọ pé óyẹ kí ìjọba gbé ìgbésẹ̀ sísọ fún àwọn tórọkan nípasẹ̀ ìlànà tó yẹ lórí gbígba ill, láti yàgò fún àhesọ.

Nígbà tón sọ̀rọ̀ lórí ìsẹ̀lẹ̀ yí, asojú ẹgbẹ tó pọ̀jù nínú ilé, ọ̀gbẹ́ni Sańjọ Adedoyin sọ pé èróngbà ìjọba láti sàmúlò àwọn saree ilẹ̀ láti mú kétò ọrọ̀ ajé rúgọ́gọ́sí, tí yò si kawọn olùdókowò wá sisẹ́ ajé lágbègbè ọ̀hún.

Ó wá rọ ìjọba láti ní àjọsepọ̀ pẹ̀lú àwọn èyàn láwọn agbègbè tí wọ́n fẹ́ lọ.

Olùdarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin wá pa lásẹ pé kí, akswé àgbà àwọn ilésẹ́ ìjọba tọ́rọkàn wá sojú sí ilẹ,  Láti sàlàyé èróngbà ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.

Kẹhinde/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *