Yoruba

Àgbéga Ètò Ẹ̀kọ́ Àti Ètò Ìrónilágbára Ló Léè Mú Àdínkù Bá Ìwà Ọ̀daràn Láwùjọ – Alága Ẹgbẹ́ Òsìsẹ́ Tẹ́lẹ̀rí

Wọ́n ti gba ìjọba àpapọ̀ nímọ̀ràn pé kí wọ́n túnbọ̀ fọwọ́ sí ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́, àti ètò ìrónilágbára àwọn èèyàn ilẹ̀ yí kópin ó lu bá ètò ààbà tó mẹ́hẹ àtàwọn ìwà ọ̀daràn míìn lọ́kọ̀kan ò jọ̀kan nílẹ̀ yí.

Alága nígbà kan rí fún ẹgbẹ́ òsìsẹ́ ilẹ̀ yí, NLC, ẹ̀ka típìnlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Ibrahim Bọlọmọpe ló sọ̀rọ̀ ìmọ̀ràn yí níbi ìdánilẹ́kọ tí àkóríẹ̀ dá lórí ìlànà ìsèjọba àwarawa ọ̀nà àbáyọ fún àyípadà àwùjọ àgbáyé èyí tó ńsàmì àyájọ́ ìjọba àwaarawa lágbayé fún tọdún yi ètò ọ̀hún ló wáyé nílé ẹgbẹ́ oníròyìn ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ tó wà ní ìyágankú ìlú ìbàdàn.

Ọ̀gbẹni Bọlọmọpe tẹnumọ́ pé, ìpèsè ètò ìsúná tó péye fẹ́ka ètò ẹ̀kọ́ pẹ̀lú àtìlẹyìn fún dídásẹ́ tara ẹni sílẹ̀ yóò mú àdínkù bá ìwà ọ̀daràn láàrin àwọn ọ̀dọ́ ti isẹ́ ohun náà yóò si jẹ́ rodò lọ mumi láàrin ìlú.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ, àarẹ ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ ilésẹ́ Radio, Mohunmaworan, àti eré orí ìtàgé nílẹ̀ yí, RATTAWU, ọ̀mọ̀wé Kabir Tsanni tọ́kasí pínpín agba ìjọba sí ẹlẹ́kajẹ̀ka gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àbáyọ ètò áàbò tó mẹ́hẹ nílẹ̀ yí.

Àarẹ ẹgbẹ́ RATTAWU, ẹni tí Ọ̀gbẹ́ni Akpausoli sojú fún sàlàyé wí pé pínpín agbára ìjọba sọ́dọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìbílẹ̀ yóò fún àwọn ẹ̀sọ́ aláàbo lẹ́sẹ̀kùkú lágbára láti lè máà fi kélé òfin gbé àwọn ọ̀daràn, tí wọ́n yóò sì máà gbé wọn lọ sílé ẹjọ́.

Alága tẹ́lẹ̀rí fẹ́gbẹ́ àwọn ìjọba ìbílẹ̀ lórílẹ̀èdè yí ẹ̀ka tìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ọmọba Abass Alẹsinlọyẹ sàlàyé wí pé ìpèsè ànfàní ìjọba àwarawa fáwọn èèyàn ẹsẹ̀kùkú lè mú àdínkù bá ìsẹ́ òhun òsì pẹ̀lú ètò ààbò tó mẹ́hẹ.

Lára ohun tó wáyé níbi ètò náà ni fífi àmì ẹ̀yẹ dá àwọn èèkàn àwùjọ lọ́lọ́ léyi tí àarẹ ẹgbẹ́ RATTAWU, Ọmọwé Kabir Tsaani wà lára wọn.

Aminat Ajibike/Babatunde Salaudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *