Yoruba

Alága Ẹgbẹ́ Ọ̀dọ́ Pè Fún Atilẹyin Àwọn Ọ̀dọ́ Lágbo Òsèlú

Wọn ti gba awọn ọ̀dọ́ ilẹ̀yí níyànjú pé kí wọ́n máà kópa tó jọjú nínú ètò òsèlú nípa darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òsèlú tó bá wù wọ́n, kí wọ́n sì ríì dájú pé wọ́n gba ìwé ìdìbò alálòpẹ́.

Alága ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ nílẹ̀yí ẹ̀ka tìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọ̀gbẹ́ni Abdulsalam Olusẹgun ló sọ̀rọ̀ ìyànjú yi nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ rẹ̀ níbi ètò ìlanilọ́yẹ̀ lórí gbígba káàdi ìdìbò alálòpẹ́ èyí tí wọ́n se àgbékalẹ̀ rẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ọgbẹni Olusẹgun ẹni tó koro ojú sí bí àwọn ọ̀dọ́ se ńfà sẹ́yìn nínú ìlànà ètò òsèlú sàlàyé wípé àwọn ọ̀dọ́ àkókò yi niti láti kópa nínú àyípadà rere ti àwùjọ nílò.

Alága ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ tún pè fún mímú àdínkù bá owó fọ́ọ̀mu olùdíje fáwọn tó bá jẹ́ ọ̀dọ́ nínú gbogbo ẹgbẹ́ òsèlú láti fi léè mú ìwúrí wá fún wọn láti kópa nínú òsèlú.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ, olùdarí àjọ elétò ìlanilọyẹ nílẹ̀ yí ẹ̀ka tìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, NOA, Arábìnrin Folukẹ Ayọọla, ẹni tí ìgbákejì olùdarí àjọ náà, Ọmọọba Sọla Sanda sojú fún, ó rọ àwọn ọ̀dọ́ pé kí wọ́n pakítímọ́lẹ̀ láti kojú ìpèníjà gẹ́gẹ́ bí asáàjú.

Arábìnrin Ayọọla tún rọ wọ́n pé kíwọ́n sá fún ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ àti pé kí wọ́n ma jẹ kí olósèlú kankan ló wọn fún ìwà jàgídíjàgan.

Ètò ìlanilọ́yẹ̀ náà asojú àjọ tó ńrísí ìdàgbàsókè ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ nípinlẹ̀ Ọ̀yọ́ tí báwọn péjú pẹ̀lú olùdámọ̀ràn pàtàkì fún gómìnà lórí ọ̀rọ̀ ọ̀dọ́ àti eré ìdárayá, Ọ̀gbẹ́ni Kazeem Bọlarinwa.

Mosọpẹ Kẹhinde/Babatunde Salaudeen

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *