Yoruba

Ìpínlẹ̀ Ògùn Bẹ̀rẹ̀ Ètò Ayẹyẹ Òmìnira Ọdún Kọkàlélọgọ́fà Ilẹ̀ Yí

Ọkan òjòkan ètò láti sàmì ayẹyẹ ọdún kọkànlélọ́gọ́ta tílẹ̀ yí gba òmìnira ló ti bẹ̀rẹ̀ nípinlẹ̀ Ògùn lóni pẹ̀lú àkànse ìrun Jímọ̀h.

Alákoso fọ́rọ̀ Ìròyìn àti Ìlànà, Ọ̀gbẹ́ni Abdulwaheed Odusile ló sọ̀rọ̀ yí di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde tí ó fi síta tó ní àkànse ìrun jimọh náà ló ti bẹ̀rẹ̀ ní Mọ́sálásí ńlá kọ̀bìtì, nílu Abẹokuta.

Ìsìn ìdúpẹ́ ayẹyẹ náà ni yio wáyé lọ́jọ́ àikú ní ilé ìjọsìn St. Peters, Ake ni áàgo mẹ́wa òwúrọ̀.

Àtẹ̀jáde náà ni ètò yíyan àwọn ọmọ ológun, ọlọ́pa, ẹgbẹ́ òsìsẹ́, àwọn akẹ́kọ káàkiri ìpínlẹ̀ Ògùn yio wáyé lọ́jọ́ ẹtì ọ̀sẹ̀ tó ńbọ̀ ní pápá ìsere M.K.O Abiọla tó wà ni kútọ̀.

Ó fikun wípé Gímìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, Ọmọba Dapọ Abiọdun rọ àwọn ọmọ ilẹ̀ yí nípáàpajùlọ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ògùn láti fààyè gba àláàfìa kí wọ́n sì sisẹ́ papọ̀ fún ìlọsíwájú orílẹ̀ èdè yí.

Sẹgun Fọlarin/Owonikoko Yẹmisi

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *