Àwọn méjìdínlọ́gbọ̀n ni wọ́n ti fàmì ẹ̀yẹ dá lọ́lá láti sàmì ayẹyẹ ọgbọ̀n ọdún ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ Ọsun.

Diẹ lára àwọn tí wọ́n fàmì ẹ̀yẹ dá lọ́lá náà lati rí alábojútó àgbà ìjọ ìràpadà Kristi, Àlúfà Enoch Adeboye, olórí àwọn ọmọ ológun tẹ́lẹ̀, Ọ̀gágun fèyìntì Alani Akinrinade, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọsun nígbàkanrí, Olóyè Bisi Akande àti àwọn Ọ̀jìnì amòfin Yusuf Ali, àti Gboyega Awomoolọ tí wọ́n jẹ́ amòfin àgbà nílẹ̀ yí eyin SAN.

Nígbàtí ó ńsọ̀rọ̀ níbi ètò náà Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Adegboyega Oyetọla rọ àwọn ènìyàn láti sisẹ́ pọ̀ láifi ìyapa ọ̀rọ̀ òsèlú wọn se ke orílẹ̀ èdè yí báà léè gòkè àgbà nítorípé àgbájọwọ́ ni a fi ńsànyà.

Gómìnà Oyetọla tó ní ètò náà se kókó wa dúró ìsẹ́jú kan fún Gómìnà alágbádá àkọ́kọ́ nípínlẹ̀ náà, olóògbe Isiaka Adeleke ti wa ní ó se pàtàkì láti mọrírì àwọn tí wọ́n ti kópa ribiribinípinlẹ̀ Ọsun.

Nígbàtí ó ńsọ̀rọ̀ níbi ètò náà, Aláàfin ti ìlú ọ̀yọ́, Ọba Lamidi Adeyẹmi gbóríyìn fún ìjọba ìpínlẹ̀ Ọsun fún fífàmì ẹ̀yẹ dá àwọn èèyàn lọ́lá nítorípé yio múkí àwọn èèyàn túbọ̀ máà lẹ́mi ìfara ẹni jìn nípáàpajùlọ àwọn ọ̀dọ́.

Adenitan Akinọla/Yẹmisi Owonikoko

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *