Bí orílẹ̀dè se ń darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀dè àgbéyé tókù láti sàmì àyájọ́ àwọn olùkọ́, àwọn tọ́rọkàn lẹ́ka ètò ẹ̀kọ́ tí rọ ìjọba nígbogbo ẹ̀ka láti se àtúngbédìde ètò ẹ̀kọ́ tó yéè koro.

Àarẹ ẹgbẹ́ àwọn òsìsẹ́ lẹ́ka ètò ẹ̀kọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ BECAN, , arábìnrin Dorcas Abuge sọ èyí nígbà tó ńbá akọ̀rìyìn ilésẹ́ Radio Nigeria sọ̀rọ̀, ó dẹ̀bi àidíró re ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ nílẹ̀ yíì ni àidárató àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, alága ẹgbẹ́ BECAN, nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ ọ̀gbẹ́ni Temitọpẹ Fatoki ni àwọn olùkọ́ láwọn ilé ẹ̀kọ́ alákọbẹ̀rẹ̀ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ àtàwọn agbègbè min nílẹ̀ Nàijírìa, ni alága gbé àwọn òsìsẹ́ nípinlẹ̀ ọ̀yọ̀, ọ̀gbẹ́ni Emmanuẹl Ogundiran, fún akitiyan rẹ̀ lẹ́ka ètò ẹ̀kọ́.

Olùkọ́ kan nílé ẹ̀kọ́ alákọbẹ̀rẹ̀, arábìnrin Ranti Ọluwẹmimọ gba àwọn olùkọ́ níyànjú láti ma sisẹ́ wọn bi sẹ láifi ti ìpèníjà yóò wù se.

Kehinde/Idogbe

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *