Yoruba

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn sèlérí láti fìyàjẹ akẹ́kọ́ọ̀ yóòwu tó bá hùwà àitọ́ láwọn ilé-ìwé

Ìjọba  ìpínlẹ̀ Ògùn ti kéde pé, wọn yóò lé èyíkèyí àwọn akẹ́kọọ tó bá domi àláfìa ìkẹ́kọ́ọ̀ rú, láwọn ilé-ìwé gbogbo tó ń bẹ nípinlẹ̀ náà kúrò nílè wé.

Alákoso fétò ẹ̀kọ́ ìmọ̀ sáyẹ̀nsì àtìmọ̀ ẹ́rọ nípinlẹ̀ Ògùn, ọ̀jọ̀gbọ́n Abayọmi Arigbabu ló sísọ lójú ọ̀rs yíì nílu Abẹokuta lákokò tón báwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí báwọn akẹ́kọọ kan nílé-ìwé girama tójẹ́ tìjọba, se ;n diya jẹ, àwọn olùkọ́ wọn nítorípé wọ́n báwọn wí.

Ó fi kálèyé rẹ̀ pé, ìjọba kòní fàayè gba ìwà àilẹ́kọ àti àiníbawí èyí tíwọ́n loit gogo sára àwọn akẹ́kọ́ọ̀ kan, ó wá sèlérí pé, ilé isẹ́ rẹ̀ yóò wankan se si èyí tó wáyé náà, tí yóò sì sèwádi ohun tó sokùnfà irúfẹ́ ìwà tíkò tọ́ ọ̀hún.

Ọjọgbọn Arigbabu gba àwọn olùkọ́ tọ́rọ̀kàn níyànjú láti yan ìwà rere tí se ẹ̀sọ́ ènìyàn láàye, bẹ́ẹ̀ ló sì tún ké sáwọn òbí náà, láti lọ máà fi ohunkohun tó bá ń bíwọn nínú nípa olùkọ́ kan, tó ọ̀gá àgbà irúfẹ́ ilé-ìwé bẹ́ẹ̀ létí, fún ìgbésẹ̀ tó bá yẹ lórí rẹ̀, lái mu ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn.

Folakemi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *