Gómìnà Ìpínlẹ̀, Èkó, ọ̀gbẹ́ni Babajide Sanwo-Olu ti pàsẹ ìgbésẹ̀ ìwádi ní kíkún lórí ohun tó sokùnfà ilé alájà mọ́kàndílógúntó dàwólulẹ̀ nípinlẹ̀ Èkó.

Àtẹ̀jádé kan tálákoso fétò ìròyìn àtáàtò gbogbo nípinlẹ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Gbenga Ọmọtọsọ, fisita, lóti tọ́kasi pé, ìgbésẹ̀ ìwádíì náà ni yóò jẹ́kí wọ́n mọ̀ ohun tó sokùnfà bílé ńlá náà se dàwó lulẹ̀, láti dènà irúfẹ́ rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

Gómìnà Sanwo-Olu wá fi àwọn èèyàn lọ́kàn balẹ̀ pé kò séwu, lórí ilé tó dàwó ọ̀hún.

Níbàyína, alábojútó àgbà, àjọ tón rí sọ́rọ̀ ilé kíkọ́ nípinlẹ̀ Èkó, ọ̀gbẹ́ni Gbọlahan Oki, sàlàyé pé, àjà mẹ́ẹ̀dógún péré ni wọ́n fọwọ́sí kíkọ́ rẹ̀ fẹ́ni tóni ilé tíwọ́n ló láti fi kọ́ ilé ọ̀hún, kó tó dipé onítọ̀hún ní kíwọ́n bá òun gbé lọ sí àjà mọ́kànlélógún.

Ọgbẹni Oki tọ́kasi, wọ́n ti lọ fi kélé òfin gbé ẹni tóni ilé náà, tíwọ́n yóò sì fi ojú rẹ̀ ba ilé ẹ̀jọ, nítorí àwọn èèyàn tó jálàisí níbi ìsẹ̀lẹ̀ ilé tó dàwó náà.

Kò sài tún fikun pé, àwọn èèyàn mẹ́rin ni wọ́n rí yọ láàye nígbà táwọn èèyàn tóti gbẹ́mi mì ti tó mẹ́fà báyíì tósì ní isẹ́ ìdóòla si ń tlsíwájú láti rí àwọn èèyàn tókùn yọ.

Àná òde yíì, ni ilé alájà mọ́kàndínlógún náà dàwó lójú ọ̀nà Gerard lágbègbè Ikoyi, nípinlẹ̀ Èkó, lákokò táwọn òsìsẹ́ ńsisẹ́ lọ́wọ́ lórí rẹ̀.

Ọkan lára àwọn òsìsẹ́ ilé náà tórí kóyọ, ọ̀gbẹ́ni Gabriel Bassey, sọ fáwọn oníròyìn pé bí áàdọta àwọn èèyàn ló sì wà lábẹ́ ilé tó dàwó náà tí wọ́n kò ti rí yọ.

Net/Fọlakẹmi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *