Igbákejì áàrẹ ilẹ̀ yíì, ọ̀jọ̀gbọn Yẹmi Ọsinbajo ti ké sáwọn ọ̀dọ́ orílẹ̀dè yíì, láti yé sàròyé lórí àwọn ìpèníjà tón kojú ilẹ̀ Náijírìa, bíkòse pé kíwọ́n mójútó ọ̀rọ̀ ọjọ́ ọ̀la wọn níbamu pẹ̀lú líláfojúsùn lórí ohun tótọ́.

Níbi ìbẹ̀rẹ̀ ìpàdé àpérò àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ yíì èyí tón sàmì àyájọ́ ọjọ́ àwọn ọ̀dọ́ ilẹ̀ adúláwọ̀ fún tọdún 2021 ló wáyé nílu Abuja.

Ilé isẹ́ ìjọba àpapọ̀ tón rí sọ́rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ àtìdàgbàsókè eré ìdárayá pẹ̀lú àjọsepọ̀ àwọn ẹ̀ka aládani ló sàgbékalẹ̀ àpérò náà.

Igbákejì áàrẹ ọ̀hún ẹni tí sojú áàrẹ Muhammadu Buhari níbi ètò náà, sọpé, ojúse gbogbo èèyàn lọ̀rọ̀ ìdàgbàsókè ilẹ́ Nàijírìa jẹ́ ìdí sìnìyí tó fi se pàtàkì fáwọn ọ̀dọ́ láti jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́.

Bẹ́ẹ́ láàra sì tún sọ fáwọn èèyàn níbi àpéjọpọ̀ náà, láti máà sàmúlò àwọn ọ̀nà tó tọ́, fúnyànjú áàwọ tàbí ìbìnú dípò lílo ìlànà rògbòdìyàn tàbí dàrúdapọ.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ, alákoso fọ́rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ àti eré ìdárayá, ọ̀gbẹ́ni Sunday Dare ké sáwọn ẹ̀ka aládani láti túbọ̀ máà dókowò sórí àwọn ọ̀dọ́.

Net/Fọlakẹmi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *