Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti fọwọ́sí àbá òfin tón se ìdásílẹ̀ ikọ̀ tí yóò máà gbógun ti ọ̀rọ̀ tó rọ̀mọ́ ìbálòpọ̀ kòtọ́ àti lásígbo akọsábo tọdún 2020 dòfin báyi.

Ọrọ ọ̀hún ló tẹ̀lé ìgbàwọlé àbọ̀ ìròyìn alága ìgbìmọ̀ tẹ́ẹ̀kótó ilé lórí ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin, arábìnrin Bimbọ Ọladeji tón sojú ẹkùn ìdìbò àríwá Ogbomọsọ nílé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.

Nígbà tón sàgbékalẹ̀ àbọ̀ ọ̀hún, Arábìnrin Ọladeji sọpé àbá òfin ọ̀hún lójẹ́ asèyọrí aláilẹ́gbẹ́ nínú ìgbìyànjú àti fòpin sí èyíkèyí làsígbo nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Gẹ́gẹ́ bóse tẹ̀ síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, okọ̀ tọrọkan, ohun ibùdó tí yóò máà sàmójútó ọ̀rọ̀ náà ni yóò máà sisẹ́ lórí ètò gbogbo tó rọ̀mọ́ wíwagbò tẹkun fún lasigbo akọsábo nípinlẹ̀ yi.

Lara Ayọade/Ayodele Ọlaọpa

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *