Àwọn tówà nípò ìsàkóso, àwọn adarí ẹ̀sìn, àwọn ọmọ ìjọ Anglican, àwọn olùkọ́ ẹbí àti ọ̀rẹ́ ẹni tíìse Bisọbu ìjọ Anglican ẹkùn àríwá ìbàdàn, ẹni ọ̀wọ̀ ọ̀mọ̀wé Sẹgun Okubadejọ ni wọ́n péjú pésẹ̀ sínú gbọ̀gàn Banquet tówà nílé ìtura Premier ìbàdàn fún ayẹyẹ ìfilọ́lẹ̀ ìwé ti ìránsẹ́ ọlọ́run náà kọ.

Nígbà tí wọ́n fọ̀rọ̀ wa lẹ́nu wò, Bisọbu ẹkùn àríwá ìjọ Anglican náà, ẹniọwọ Sẹgun Okubadejọ sọpé ìwé tí òhun kọ tóhun pe akori ẹ̀ ní “Waste Grace” lójẹ́ kíkọ pẹ̀lú àwọn ìpèníjà àwùjọ àti tọrọ ajé t;i koti lójùtú látọwọ́ ìjọba tó ń bẹ níta nílẹ̀ Nàijírìa.

Nínú ọ̀rọ̀ wọn, olùbádámọ̀ràn pàtàkì sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Benue lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ọ̀gbẹ́ni Blessed Omar àti ẹni tíìse alámojútó ètò ẹ̀kọ́ nípinlẹ̀ Òndó, ọ̀gbẹ́ni Fẹmi Agagu kọminú lórí ọ̀rọ̀ àisetò àbò nílẹ̀yí pẹ̀lú pípè fún àgbajọ́ọ̀wọ́ táà fi sọ̀yà lórí ìpèníjà náà.

Sáàjú nínú ọ̀rọ̀ ẹni tíìse adarí ọ̀rọ̀ ìkànsáràlú àti alámojútó ètò ìròyìn fún ìjọ Anglican ẹkùn àríwá ìbàdàn, ọ̀gbẹ́ni Ademọla Afọlabi lóti sọpé ìwé náà lójẹ́ irinsẹ́ pàtàkì fún wíwá ojútu sí ọ̀pọ̀ ìpèníjà tón kojú ilẹ̀ Nàijírìa.

Nígbà tón sàgbéyẹ̀wò ìwé náà, ẹni tíìse olóòtu ìwé ìròyìn Punch nígbàkanrí, ọ̀gbẹ́ni Bọla Bọlawọle sàlàyé pé ònkọ̀wé náà sàgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ ìwà àjẹbánu, ọ̀wọ́ngógó ǹkan, àisetò àbò, díkẹnukọlẹ̀ àwọn ohun amáyédẹròn, àisiwa ọmọluabi na láwùjọ àisísẹ́ se, isẹ́ òhun òsì, tófimọ́ báwọn olósèlú tíkòní àfojúsùn rere se n parọ́ arawọn sórí ipò àti sísàwárí ohun àmúlò àwọn ọrọ̀ tó sodo sílẹ̀yí.

Ẹwẹ olúbàdàn ilẹ̀ ìbàdàn ọba Saliu Adetunji tí Balogun ilẹ̀ ìbàdàn, Olóyè Owolabi Ọlakunlehin sojúfún sàlàyé pé ìwè náà ló bọ́ sásìkò fún wíwá ojútu sí àwọn ìsoro ilẹ̀ Nàijírìa.

Lara Ayọade/Ayodele Ọlaọpa

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *