Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti ní kanse isẹ́ iná ọba aládani tíìjọba òun gùnlé yio wa láti pèsè iná ọba fún ile ìjọba, àwọn ilé ìwé ilé ìwòsàn, àwọn iná ojúpópó àti pápá ìseré láiyọ àwọn ibi tó se kókó min sélẹ̀.

Ó sọ̀rọ̀ yí níbi àkànse ìsìn ìdúpẹ́ tó wáyé ní ilé ìjọsìn onítẹ̀bọ̀mi tó wà ní igbójàyè tó wà níjọba ìbílẹ̀ ilétẹ̀síwájú nípinlẹ ọ̀yọ́.

Ó fikun wípé ìjọba tí òun ńdarí yio tẹ̀síwájú láti máà sàmúlò àwọn ànfàní ti ẹkùn oke Ògùn ni tó nínú, isẹ́ ọ̀gbìn, ìrìn àjò afẹ́ ohun àlùmọ́nì àti okòòwò.

Sáàjú nínú ìwásùn rẹ̀, ààrẹ fún àgbáríjọ àwọn ìjọ onítẹ̀bọ̀mi lókè Ògùn, ẹniọwọ, ọ̀mọ̀wé Gabriel Ọlanrewaju ni orílẹ̀ èdè yí nílò àwọn asáàjú tó see fọkàn tán láti léè làlùyọ níní àwọn ìpèníjà tó ńkojú rẹ̀ ó fikun wípé àwọn adarí yi tún gbọ́dọ̀ ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run nínú ohun gbogbo tí wọ́n bá ńse.

Rotimi Famakin/Folakemi Wojuade

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *