Àarẹ Muhammade Buhari ti buwọ́lu àbádòfin ètò ìsúná àpapọ̀ tiriliọnu mẹ́tàdínlógún ólé diẹ ìyẹn 17.126 TN fọ́dún 2022.

Àarẹ buwọ́lu àbá ètò ìsúná tí olùbádámọ̀ràn àgbà rẹ̀ lórí ọrọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin Sẹnator Babajide Omoworare gbé síwájú ẹ̀ nílé gbe àarẹ nílu Abuja tíse olú ìlú ilẹ̀ yí.

Àarẹ Buhari yànàná àwọn apá ibí tón komulominu lórí àyípadà tódi àbá ètò ìsíná náà, tófimọ́ àlékún biliọnu lọ́nà iriwó naira, àdínkùn àdápadà àlàkalẹ̀ owóya pẹ̀lú biliọnu lọ́nà méjìlélógún àtàwọn nkan min.

Àarẹ kòsài tún sọ̀rọ̀ lórí àfikún owóna àpapọ̀ biliọnu mẹ́rìndínlólógì ólé diẹ̀ fún isẹ́ àkànse ilé ìgbìmọ̀ asò fin ilẹ̀ yí eléyi tó sàlàyé pé ó tako ìlànà àgbékalẹ̀ pínpín isẹ́ láàrin igunsígu ìjọba.

Gẹ́gẹ́ bárẹ se wí, óní ọ̀pọ̀ àkànse isẹ́ tówà nínú àbá ètò ìsúná náà lójẹ́ ojúse àwọn ìpínlẹ̀ àti ìjọba ìbílẹ̀.

Níparí ọ̀rọ̀, àrẹ ó wá sèlérí láti tètè bèrè àgbékalẹ̀ àbá ètò ìsúná tó kángun sí fífa ìjọba lera enilọwọ fọdún 2023 pẹ̀lú àgbékalẹ̀ ìlànà ètò ẹ̀náwó ọdún 2023 sí ọdún 2-25 fúnle ìgbìmọ̀ asòfin.

Ayodele Ọlaọpa.

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *