Yoruba

Gómìnà Makinde pè fún ìkúnlọ́wọ́ fáwọn tó kù diẹ káato fún láwùjọ

Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti késí àwọn aráàlu, àwọn ilé isẹ́, àwọn ẹlẹ́yinjú anu, lájọlájọ àtàwọn min tọ́rọnkàn lórí síse ìkúnlọ́wọ́ fúnjọba fún ìgbáyégbádùn àwọn tókùn diẹ káàto fún nípinlẹ̀ yí.

Gómìnà pe ìpè náà lásìkò ayẹyẹ fífa ilé gbe àwọn ọkùnrin ohun ófìsì tódi títúnse ní ọgbà àtúnse àwọn mọ̀jèsín àti ti ìtọ́jú àwọn ògo wẹrẹ tówà lágbègbè ijokodo pẹ̀lú ọwọ ọrẹ ibùsùn látọ̀dọ̀ bánki kan.

Gómìnà Makinde tí àkọ̀wé àgbà ilé isẹ́ tówà  fọ́rọ̀ àwọn obìnrin ohun ọrọ àwùjọ, arábìnrin Christiana Abioye sojúfún sàlàyè pé rírísí ìgbáyégbádùn àwọn tó ku diẹ káto fún láwùjọ ni yóò fún wọn nírètí ọjọ́ ọ̀la tó dára.

Nígbà tó ń sàpèjúwe ìgbésẹ̀ bẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwà sise anu, Gómìnà Makinde sọpé dídásí ọ̀rọ̀ àwùjọ pẹ̀lú nínawọ́ ọrẹ lójẹ́ ìwà tó da gba.

Ayodele Ọlaọpa  

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *