Yoruba

Àarẹ Muhammade Buhari ti buwọ́lu àbádòfin ètò ìsúná àpapọ̀ tiriliọnu mẹ́tàdínlógún ólé diẹ ìyẹn 17.126 TN fọ́dún 2022.

Àarẹ buwọ́lu àbá ètò ìsúná tí olùbádámọ̀ràn àgbà rẹ̀ lórí ọrọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin Sẹnator Babajide Omoworare gbé síwájú ẹ̀ nílé gbe àarẹ nílu Abuja tíse olú ìlú ilẹ̀ yí.

Àarẹ Buhari yànàná àwọn apá ibí tón komulominu lórí àyípadà tódi àbá ètò ìsíná náà, tófimọ́ àlékún biliọnu lọ́nà iriwó naira, àdínkùn àdápadà àlàkalẹ̀ owóya pẹ̀lú biliọnu lọ́nà méjìlélógún àtàwọn nkan min.

Àarẹ kòsài tún sọ̀rọ̀ lórí àfikún owóna àpapọ̀ biliọnu mẹ́rìndínlólógì ólé diẹ̀ fún isẹ́ àkànse ilé ìgbìmọ̀ asò fin ilẹ̀ yí eléyi tó sàlàyé pé ó tako ìlànà àgbékalẹ̀ pínpín isẹ́ láàrin igunsígu ìjọba.

Gẹ́gẹ́ bárẹ se wí, óní ọ̀pọ̀ àkànse isẹ́ tówà nínú àbá ètò ìsúná náà lójẹ́ ojúse àwọn ìpínlẹ̀ àti ìjọba ìbílẹ̀.

Níparí ọ̀rọ̀, àrẹ ó wá sèlérí láti tètè bèrè àgbékalẹ̀ àbá ètò ìsúná tó kángun sí fífa ìjọba lera enilọwọ fọdún 2023 pẹ̀lú àgbékalẹ̀ ìlànà ètò ẹ̀náwó ọdún 2023 sí ọdún 2-25 fúnle ìgbìmọ̀ asòfin.

Ayodele Ọlaọpa.

News Yoruba

Aareorileede yi Muhaamadu Buhari ti ki awon Musulumi to n be jake jado ile ati ni gbogbo agbaye ku oriire ayeye ojoibi Anobi Muhamodu tiwon tun foju gan-an ni re lodun yi.

Eyi to jeyo ninu atejade kan takowe agba feto iroyin fare, Mallam Garba Shehu fisita ninu oro to firanse eti to na sami ayeye ojo ibi Anobi Mohammod, nibe laare Buhari ti ro awon Musulumi lati maa toro aforijin ese won lado Olohun Oba Allah, kiwon si maa jeki igbeaye ateko tojise nla Muhammod fi koni, maa han ninu ise awon lojoojumo.

Ko sai tun lo akoko naa fi pakiyesi awon eeyan si bawon ajo alaabo gbogbo se fikun akitiyan won ni idahun seto abo to mehe nile yi.

Bee lo si ke sawon ile-ise iroyin gbogbo lati maa jabo ojulowo iroyin nipa igbiyanju ati fopinseto abo to mehe, atawon igbese ona abayo.

Gege bare se wipe, ifowosowop atajosepo to wa laarin awon eeyan pelu awon Olopa to fun awon tawon omo ologun lo seranlowo lenu igbese aseyori tawon tise lati pin wo iwa odaran ati sisawolu kumo-kumo

Okareh/Wojuade

Yoruba

Àrẹ Muhammade Buhari ti sọ pé àmúgbòrò yo de bá ìgbáyé gbádùn àwọn èyàn nílẹ̀ Nàijírìa, bẹ̀rẹ̀ nípa ìpèsè ètò àbò tó múnádóko.

Nílu Maiduguri, l’afin Shehu ti Borno, ni àrẹ ti sọ̀rọ̀ ìdánilójú yi .

Àrẹ ẹni tó ń se àbẹ̀wò ẹnu isẹ́ ọlọ́jọ́ kan sípinlẹ̀ Borno, ló ti kọ́kọ́ se ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú okọ̀ ológun tó wà lágbègbè ọ̀hún.

Óní ìpinu òun láti sin àwọn èyàn orílẹ̀èdè yí, ló wà tatara ifẹ̀ tí wọ́n fihàn sí, bẹ lótún gbóríyìn fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno lórí akitiyan rẹ̀ láti mú ìdàgbàsókè bá ìpínlẹ̀ náà láiwo ìpèníjà lórí àbò tí wọ́n ńlà kọjá.

Nínú ọ̀rọ̀ Shehu tílù Borno, àlhájì Abubakar El-kanemi, dúpẹ́ lọ́wọ́ àrẹ lórí idahun sí ìbere àwọn èyàn ìpínlẹ̀ náà, pẹ̀lú àtọ́kasí pé ètò àbò tin rẹsẹ̀ walẹ̀ sí nípinlẹ̀ ọ̀hún.

Ọlọlade Afọnja

Yoruba

Aare Muhammadu Buhari ti tepepe iwe eto isuna to le ni tirilionu metala naira fodun 2021 funle Igbimo Asofin apapo.

Aare Buhari lo te pepe iwe eto isuna na fun ile Asofin apapo mejeeji to wa nijoko.

O soo di mimo pee eto isuna odun 2021 lo duro le igbende eto oro aje nipa ati mu eto oro aje ile yi pada bo sipo.

Aare soo di mimo pe, ipenija gbogi to n koju ijoba to wa lodo ko seyin ona ipawo wole sapo ijoba, o se afikun e pe ijoba apapo ti ri akosile rere nidi ogbin iresi.

Saaju ni Aare Ile Asofin Agba, Senator Ahmed Lawan ti salaye pe aba eto Isuna odun 2021 ni eto to peye yi wa fun pelu amojuto ohun amusoro to w anile fun idagbasoke ile Nigeria.

Idogbe