Yoruba

Àwọn akẹ́kọ wọlé fún sáà ètò ẹ̀kọ́ kejì nípinlẹ̀ ọ̀yọ́

Ètò ìkẹ́kọ ti bẹ̀rẹ̀ láwọn iléèwe ìjọba àti aládani tó wà nígbogro ìlú ìbàdàn.

Akọ̀ròyìn Radio Nigeria tó lọ káàkiri jábọ̀ wí pé àwọn akẹ́kọ ti péjú sọ́gbà iléèwe wọn láàrọ òní pẹ̀lú isẹ́ ìmọ́tótó àyíká iléèwe wọn fún ìkẹ́kọ sáà tuntun.

Ó sàkíyèsi wípé ní iléèwe Girama Ọba Akinbiyi tó wà ní Mọ́kọ́lá àti iléèwe Girama Jẹricho tó wà ní Ìdí-ishin, àwọn akẹ́kọ àti olùkọ́ péjúpésẹ̀ sọ́gbà àwọn iléèwe náà.

Olùkọ́ kan nílèèkọ Girama Jẹricho sàlàyé wípé àwọn tiwà nígbaradì láti bẹ̀rẹ̀ ètò ìkẹ́kọ fún sáà kejì.

A ó rántí pé, ọjọ́ kẹtàdínlógún osù kejìlá ọdún tó kọjá làwọn iléèwe bẹ̀rẹ̀ ìsinmi láti fi yayọ̀ òpin ọdún tó kọjá.

Famakin/ Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *