Yoruba

Iná se ọsẹ́ lọ́jà Agbeni

Kò dín ní ilé ìtàjà mẹ́rin tó jóná lówurọ̀ òní lágbóòlé Jámọjẹ ní Agbéní nílu ìbàdàn nínú ìjàmbá iná èyítí ó bẹ́ sílẹ̀ ní kùtù kùtù áàrọ yi, tí gbogbo ìsápá àwọn olùgbé agbègbè náà àti àwọn òntàjà láti paná ohun jásí pàbó.

Akọ̀ròrìn ilésẹ́ Radio Nigeria jábọ̀ pé títẹ̀lé dé ti àwọn òsìsẹ́ panápaná ìjọba àpapọ̀ tètè dé síbi ìsẹ̀lẹ̀ náà ló dẹ́kun iná yí tí kò jẹ́ kó tàn dé àwọn ilé ìtàjà yokù àti ibití àwọn èèyàn ńgbé.

Ọkan lára àwọn olùgbé agbègbè náà, ọ̀gbẹ́ni Kẹhinde Ayinla àti òntàjà kan, ọ̀gbẹ́ni Musa sọ wípé wọ́n o léè sọ ní pàtó ohuntí ó fa ìjànbá iná ọ̀hún.

Ọga àgbà ilésẹ́ panápaná tó wà ní Gbági, ọ̀gbẹ́ni Jimọh Musbau sàlàyé pé ní kété tí wọ́n gba ìpè lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà ni wọn gbéra àmọ́ tí ilé ìtàjà mẹ́rin tí jóná kí wọ́n tóò dé.

Akọ̀ròrìn ilésẹ́ Radio Nigeria tún jábọ̀ pé, àwọn òsìsẹ́ àjọ áàbò ara ẹni lààbò ìlú NSCDC náà wà lárọwótó láti fẹsẹ̀ ètò áàbò múlẹ̀ lọ́nà àti dènà àwọn jàndùkú láti fànfàní náà máà fọ́ ìsọ̀ ìtàjà.

Famakin/Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *