Ijoba apapo ti soo di mimo wi pe won yoo se idasile ebu ifopo esekuku meta otooto si okookan ati ipinle to n pese epo robi lagbegbe Niger/Delta.

Alakoso keji foro ayika nile yi, Oloyo Sharon Keazor lo sipaya oro yi ninu atejade to fi sita nilu Abuja.

O salaye wipe, awon ebu ifopo meta yi yoomu ona abayo wa fawon onise owo to n fi ise ebu ifopo se ise oojo, ti yoo si tun fun won lanfaani ati jawo ninu fifo epo robi lona ti ko bofin mu.

Alakose naa tenumo pea won ebu ifopo alabode yi ni won yio ti maa se amulo ohun elo ti won pese labele pelu awon ileese ijoba to je akosemose bii ileese ijoba apapo to wa fun ohun alumoni epo robi, ile sko giga fasiti ijoba apapo to wa fun epo petirolu, eyi to wa nilu effurun ati ile eko giga fasiti Ahmadu Bello to wa nilu Zaria.

Gege bo se wi, ijoba apapo yoo tun seto idanileko fawon onise owo ti yoo maa fo epo naa nipa amojuto ayika, lona tise won yoo fi pegede.

Babatunde Salaudeen

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *