Yoruba

Adari ile asofin apapo keji Ogbeni Femi Gbajabiamila tip e fun idasile Banki eto eko lona ati le maa pese owoya irorun ti ko ni ele fawon akeko to wa nile eko giga nipa ati le mu eto eko rorun fun tolori telemu.

Adari ile asofin tun pe fun agbende liana eto eyawo fawon akeko lorileede yi.

Ogbeni Gbajabiamila lo pepe yi nilu Eko lasiko idanileko kan to se pelu alaye wipe opo ibeere lo n waye lori ipese eto isuna fawon ile eko giga, leyi to le je ki ala ojo iwaju rere awon akeko to je, olopolo pipe wa ninu ewu nitori isoro oda owo.

Asofin naa tanmole si wi pe abadofin akeko, leyiti won yoo fi odun keji san pada leyin ti won ba pari eto isinru ilu.

Babatunde Salaudeen

Yoruba
 

Ijoba apapo ti soo di mimo wi pe won yoo se idasile ebu ifopo esekuku meta otooto si okookan ati ipinle to n pese epo robi lagbegbe Niger/Delta.

Alakoso keji foro ayika nile yi, Oloyo Sharon Keazor lo sipaya oro yi ninu atejade to fi sita nilu Abuja.

O salaye wipe, awon ebu ifopo meta yi yoomu ona abayo wa fawon onise owo to n fi ise ebu ifopo se ise oojo, ti yoo si tun fun won lanfaani ati jawo ninu fifo epo robi lona ti ko bofin mu.

Alakose naa tenumo pea won ebu ifopo alabode yi ni won yio ti maa se amulo ohun elo ti won pese labele pelu awon ileese ijoba to je akosemose bii ileese ijoba apapo to wa fun ohun alumoni epo robi, ile sko giga fasiti ijoba apapo to wa fun epo petirolu, eyi to wa nilu effurun ati ile eko giga fasiti Ahmadu Bello to wa nilu Zaria.

Gege bo se wi, ijoba apapo yoo tun seto idanileko fawon onise owo ti yoo maa fo epo naa nipa amojuto ayika, lona tise won yoo fi pegede.

Babatunde Salaudeen