Àjọ ẹ̀sọ́ ojú pópó, FRSC, ti ní lílo ìlànà ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé tí múkí ọwọ́ isẹ́ túbọ̀ yá kánkán àti jáfáfá síì léyití ó ti jẹ́kí àdínkù dé bá àwọn ìjàmbá ojú pópó.

Ọga àgbà àjọ FRSC, ọ̀mọ̀wé Boboye Oyeyẹmi ló sọ̀rọ̀ yí di mímọ̀ níbi ìdánilẹ́kọ kan tó wáyé nílu Abuja.

Ọmọwe Oyeyẹmi wá tẹ́ pẹpẹ oníruru ọ̀nà tí àjọ náà ti sàmúlò ìlànà ìgbàlódé nínú ìgbà sísẹ́ rẹ̀ láyití ó ní nínú ẹ̀rọ tí yio jẹ́kí wọ́n máà léè wòye bí àwọn ọkọ̀ tise ńsáré lójú pópó àti síse ìwé àsẹ ìwakọ̀ lọ́nà ìgbàlódé.

Ó wá wòye pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ yí ni wọ́n o tẹ́wọ́ gba àyípadà tó ńbá ọ̀nà ìgbà sisẹ́ wọn àmọ́ tí àjọ náà ti ńlawọn lọ́yẹ̀ lórí ìdí tó fi se pàtàkì láti fáàyè gba àyípadà rere.

Oluwayemisi Owonikoko

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *