Àbá òfin láti sàyípadà ilé ẹ̀kọ́ gíga ìmọ̀ ẹ̀rọ Ládòkè Akintọla, LAUTECH, sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ńkọ́ ìmọ̀ gbogbogbò ni wọ́n ti kà fún ìgbà kejì nílé ìgbìmọ̀ asòfin Ìpínlẹ́ ọ̀yọ́.

Èyí ló jẹ́ nítorí ìwé kan tí Gómìnà Seyi Makinde fi sọwọ́ sílé ìgbìmọ̀ asòfin tí adarí ilé, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin kà níbití Gómìnà ti ńbèèrè fún àyípadà ilé ẹ̀kọ́ gíga ọ̀hún.

Nígbàtí wọn ńjìròrò lórí àbá òfin náà asòfin tó ńsojú ẹkùn àríwá Ògbómọ̀sọ́, Arábìrin Ọlawunmi Ọladeji ní orúkọìlú tó gba ilé ẹ̀kọ́ náà lálejò gbódọ̀ hàn nínú orúkọ rẹ̀ bí wọ́n se fẹ sọ ilé ẹ̀kọ́ gíga náà di elékan kan.

Ó wá dába kí wọ́n sọ́ọ̀ ní ilétẹ́kọ gíga Ladoke Akintọla, Ògbómọ̀sọ́ dípò ilé ẹ̀kọ́ gíga Ladoke Akintọla lasán tí ẹ̀ka alásẹ dába.

Nígbàtí ó ńfèsì, ọ̀gbẹ́ni Adebọ Ogundoyin ní àbá òfin náà jẹ́ lára ìgbésẹ̀ ìjọba tó wà lóde báyi láti sàtúnse ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ nípinlẹ̀ ọ̀yọ́.

Mosope Kehinde/Oluwayemisi Owonikoko  

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *