Yoruba

Ẹgbẹ́ Àwọn ọmọ Ilẹ̀ Yí Nílẹ̀ Òkèèrè Bèèrè Fátìlẹyìn Ìjọba Lórí Àwọn Akẹ́kọ Tó Sá Kúrò Ní Ukraine

Alága ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàijírìa lókèèrè, ẹ̀ka ti orílẹ̀ èdè Hungary, ọ̀mọ̀wé Hussaini Argungun ti bèèrè fún àtìlẹyìn ilésẹ́ ìjọba àpapọ̀ fọ́rọ̀ amujo ìjàmbá àti mímú ìdẹ̀rùn bá ará ìlú lórí àwọn akẹ́kọ ọmọ olẹ̀yí tí wọ́n sá kúrò ní Ukraine kí wọ́n báà le dúró ní Hungary.

Ọmọwe Argungun ẹnití ó ńbá ilé ẹ̀kọ́ gíga kan nílẹ̀ Hungary sisẹ́ ní ẹgbẹ́ àwọn ti ńpín óunjẹ fáwọn akẹ́kọ náà pẹ̀lú àtìlẹ́yì oníruru àwọn àjọ tí kíìse tìjọba.

Gẹ́gẹ́bí ọmọbíbí ìpínlẹ̀ Kẹbbi náà sesọ ótó igba àwọn akẹ́kọ náà tí wọ́n padà sí Nàijírìa ni wọ́n si ńretí kí wọ́n wá kó wọn ní Hungary, àmọ́ tó ní ọ̀pọ̀ nínú àwọn akẹ́kọ náà ni wọ́n wà nípele tó kẹ́yìn ẹ̀kọ́ wọn tí wọ́n ti ńkọ́ nípa ìmọ̀ ìsègùn tí wọ́n sì ti fífẹ́hàn àti dúró ní Hungary pẹ̀lú ìrètí wípé àwọn ilé ẹ̀kọ́ ilẹ̀ náà yio gbà wọn láti pári.

Ọmọwe Argungun fikún wípé àwọn kan nínú àwọn akẹ́kọ náà ni wọ́n ńfarapamọ́ sáwọn ilé ìjọsìn, àti àwọn ilégbe min táwọn àjọ tí kiise tìjọba pèsè.

Níbàyí náà, ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ tí wọ́n sá kúrò ní Ukraine, Philip Bankọle tíì se akẹ́kọ ìpele tó kẹ́yìn inú ìmọ̀ ìsègùn ni kiev sọ wípé ìrètí òun ni láti parí ẹ̀kọ́ òun kí òun tó padà wa sílẹ̀ yí.

Ọgọọrọ àwọn akẹ́kọ ọmọ ilẹ̀ yí tí wọ́n sá lọ sí Poland, Hungary àti Romania ni wọ́n ti gbé wá padà sílé láti ìgbàtí ogun ti bẹ́ sílẹ̀ ní Ikraine.

Oluwayemisi Owonikoko

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *