Ọkọ̀ agbepo kan tó kún fún epo bẹntirol ti da ẹrù rẹ̀ nù lágbègbè Dangote, tó wà ní ìdígba Ilọra lópopónà másọsẹ̀ ọ̀yọ́ sí ìbàdàn, èyítí ó ti fi àwọn awakọ̀ àti olugbé ibẹ̀ sínú ewu.
Akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria ríì gbọ́ wípé awakọ̀ epo nà ni wọ́n ti gbé lọ sí iléwòsàn lásìkò tó farapa bí ọkọ̀ náà ti fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ bó séè ńgbìyànjú àti bọ́ sóri títì másọsẹ̀ ní kùtùkùtù òwúrọ̀ òní.
Àwọn èèyàn, ní páàpajùlọ àwọn ọlọ́kadà ni wọ́n yabo ibẹ̀ láti gbọ́n epo tí wọ́n sì ńsèdíwọ́ fáwọn òsìsẹ́ panápaná tí wọ́n fẹ́ dènà ìjànbá iná níbẹ̀.
Òsìsẹ́ ilé isẹ́ panápaná kan, ọ̀gbẹ́ni Jonhson Odewabi enití ó bá akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria sọ̀rọ̀ níbití ìsẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé sọ èrò ọkàn rẹ̀ lórí iha tí àwọn èèyàn kò sọ̀rọ̀ ààbò.
Akọ̀ròyìn ilésẹ́ Radio Nigeria jábọ̀ wípé kòsí òsìsẹ́ aláàbo kankan níbi ìsẹ̀lẹ̀ ọ̀hún lásìkò tó ńkó ìròyìn jọ.
Ọga àgbà ilésẹ́ ọlọ́pa lẹ́kùn Ilọra, ọ̀gbẹ́ni Philip Abayọmi enití ó bá akọ̀ròyìn ilésẹ́ wa sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ sọ wípé àwọn òsìsẹ́ ilésẹ́ ọlọ́pa kò ní pẹ́ dé ibẹ̀.
Oguntọna/Yẹmisi Owonoko


