Ẹgbẹ́ àwọn akọ́sẹ́mọsẹ́ lórí adójútófo nílẹ̀ yí CIIN ẹ̀ka tìpińlẹ̀ ọ̀yọ́ ti búra fún àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ tuntun.

Ètò yí tó wáyé níbi ayẹyẹ ìfàmìẹ̀yẹ dáni lọ́lá àti ìgbaniwọlé ọlọ́lọọdún wọn tó wáyé nílu ìbàdàn ni wọ́n ti búra fún ọ̀gbẹ́ni Ọladeji Akinọla gẹ́gẹ́bí alága àti àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ mẹ́jọ min tí wọn yio tukọ̀ ẹgbẹ́ fún ọdun kan.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọ̀gbẹ́ni Akinọla sèlérí àti sisẹ́ lé àwọn àseyọrí tí àwọn tó ńfipò sílẹ̀ se, àti láti kọ́ olúlé ẹgbẹ́ fún ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.

Nínú ọ̀rọ̀ tìẹ, bàbá ìsàlẹ̀ ẹgbẹ́ náà, Olóyè Babajide Ọlatunde Agbeja rọ àwọn òsìsẹ́ elétò adójútófo láti máà tẹ̀lé àwọn ohuntí òfin isẹ́ wọn sọ kí wọ́n sì máà tètè san ẹ̀tọ́ àwọn oníbarà wọn tó yẹ.

Sáàjú ni alága níbi ayẹyẹ náà tíì sí igbákejì Gómìnà nípinlẹ̀ ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀, Olóyè Iyiọla Ọladokun ẹnití olóyè Alani Ọlọjẹde sojú fún tẹnumọ́ ìdí tó fi sepàtàkì fáwọn ọmọ ilẹ̀ yí láti máà kówólé ètò adójútófo.

Lára àwọn ohuntí ó wáyé níbi ayẹyẹ náà láti fifi àmì ẹ̀yẹ dá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó peregedé àti àwọn tó ti làmì láàka láwùjọ lọ́lá.

Kehinde Mosọpẹ/Yẹmisi Owonoko

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *