Àwọn ẹlẹ́ri Jèhófà nílẹ̀ yí àti káàkiri àgbáyé ni wọn yio si gbọ̀gàn ìpàdé wọn padà lọ́jọ́ ẹtì ọ̀sẹ̀ yí lẹ́yìn tí wọ́n ti gbéè tì padà fún bíì ọdún méjì níbamu pẹ̀lú ìlànà áàbò àti dènà ìtànkálẹ̀ àrùn covid 19.
Àtẹ̀jáde látọ̀dọ̀ olú ile isẹ́ àwọn ẹlẹ́ri Jèhóvàh sọ wípé àkànseàsọyé ọlọ́gbọ̀n ìsẹ́jú tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “ Níbo láti léè ríì ìrètí tó dájú”ni yio wáyé láwọn gbọ̀ngàn ìpàdé káàkiri àgbáyé.
Àtẹ̀jéde náà wá rọ àwọn ènìyàn láti péjú pésẹ̀ fún àkànse ètò ìrántí ikú Jésù Olúwa ní àsálẹ́ ọjọ́ ẹtì ọjọ́ kéèdógún osù tónbọ̀.
Àtẹ̀jáde náà fikun wípé ko sí ètò ìforúkọsílẹ̀ fáwọn ètò méjèèjì wọ́nyí, bí Wọ́n bá si fẹ́ ìdáhùn si ìbéère lórí àwọn ètò wọ́nyí wọ́n léè rí lóri àtẹ ẹ̀rọ ayélujára ni ìtàkùn www.jw.org.
Nafiu Busari/Oluwayemisi Owonikoko


