Àarẹ Muhammadu Buhari ti kí ikọ̀ agbágbbọ̀ọ̀lù Super Falcons kú oríìre àseyọrí wọn nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn pẹ̀lú ikọ̀ Indomitable Lioness ti Cameroon pẹ̀lú àmì ayò kan sí òdo nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ìpele kejì tó kángun sí àsekágbá níbi ìdíje ife ẹ̀yẹ ilẹ̀ adúláwọ̀ tàwọn Obìnrin tọdún 2022 tó ńlọ ní Morocco.

Àtẹ̀jáde látọ̀dọ̀ amúgbálẹ́gbẹ àarẹ lórí ìròyìn àti ìpolongo, ọ̀gbẹ́ni Adesina ni àarẹ gbóríyìn fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Falcon fún bí wọ́n ti se jà fitafita láti ráàye nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tàwọn obìnrin tọdún tó ńbọ̀.

Bákanàà ni alákoso fọ́rọ̀ eré ìdárayá Sunday Dare nígbàtí ó yọ́ lórí àseyọrí àwọn agbábọ́ọ̀lù lóbìnrin rọ wọ́n láti túbọ̀ fikún ìsapá wọn láti jáwé olúborí fún ìgbà kẹwa nínú ìdíje tó lọ lọ́wọ́.

Oluwakayode Banjọ/Yemisi Owonikoko

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *