Àarẹ ilẹ̀ America, Joe Biden ni yio se pàdépọ̀ pẹ̀lú àwọn adarí ilẹ̀ Palestine tí wọ́n wà lágbègbè West Bank lóni sáàjú kó tó lọ síbi ìpàdé àpérò ni Saudi Arabia.

Gẹ́gẹ́bí ohuntí àwọn ònwòye sọ, ó seese kí ǹkan lọ́ jái níbi ìpàdé náà pẹ̀lú Mahmoud Abbas nítorí gbúngbùngbún tó wà láàrin wọn pẹ̀lú ìsèjọba àarẹ Trump.

ọ̀gbẹ́ni Biden yio tún sèpàdépọ̀ pẹ̀lú adarí ilẹ̀ Saudi Arabia, Ọmọba Mohamined bin Salman àti bàbá rẹ, ọba Salman níbití wọ́n yio ti gíròrò lórí ìpèsè iná ọba, ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀  lórí ọ̀rọ̀ ààbò.

Ao mu wá sí ìrántí wípé àarẹ Biden ti sèlérí a kojú oro sí orílẹ̀ èdè Saudi Arabia nítorí ìsekúpani oníròyìn Khasinoggi látọwọ́ àwọn òsìsẹ́ ilẹ̀ Saudi lọ́dún 2018.

BBC/Yemisi Owonikoko

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *