News Yoruba

Àarẹ Muhamadu Buhari ti pàsẹ fáwọn àjọ aláàbo nílẹ̀yí láti tẹ̀síwájú lórí gbígbógun ti àwọn ẹni láàbi tó ń pagidínà ètò àbò títí tọ́rọ̀ náà yóò fi dafi seyi tẹ́ẹ̀gun alarẹ fisọ.

Àarẹ sọ̀rọ̀ náà nílu Abuja lásìkò àbẹ̀wò àwọn olórí ilé isẹ́ èètò àbò sí lórí ibi tí ń kan dé dúró, àti àwọn àdojúkọ wọn fún isẹ́ ètò ààbò, papajùlọ lápá ìwọ̀-oorun àríwá àti àrin gbùngbùn àríwá nílẹ̀yí.

Nígbà tón bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdè náà, alákoso fétò àbò, ọ̀gágunfẹ̀yìntì Bashir Magashi sàlàyé pé ọ̀rọ̀ àwọn agbébọn ti di ailesọ lọrun páàka tótó àpérò fọ́mọ eriwo.

Alákoso ọ̀hún ní ìjọba si dúró lórí ipò rẹ̀, pẹ̀lú àlàyé pé ọ̀rọ̀ wíwójùtú sètò àbò jẹ́ ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ fúnjọba, àmọ́sá àgbájọwá táà fi sọ̀yà nikan lọ́nà àbáyọ nílẹ̀yí káláàfìa le jọba.

Ẹwẹ nínú ọ̀rọ̀ rẹ níbi ìpàdé náà, ọ̀gá àgbà ọlọ́pa yányán nílẹ̀yí Alhaji Usman Baba sàlàyé pé gbogbo ikọ̀ aláàbo nílẹ̀yí, yóò fimọ sọ́kan láti fikun akitiyan wọn, tó sèpèjúwe gẹ́gẹ́bí èyí tó ti n kẹ́sẹjárí.

Ayọade/Ọlaọpa

Yoruba

Bí àwọn Mùsùlùmí lórílẹ̀èdè yíì, se darapọ̀ mọ́ àwọn akẹgbẹ́ wọn lágbayé láti sayẹyẹ ọjọ́ ìbí ànọ́ọ̀bì.

Àarẹ Muhammadu Buhari ti rọ àwọn èèyàn ilẹ̀ yíì láti sàmúlò àkókò yíì, fíì nawọ́ ìfẹ́ sáwọn èèyàn wọn gẹ́gẹ́ bí àwòkóse ànọ́bì.

 Nínú àtẹ̀gáde tí olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún àrẹ lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn àti ìbáráalu sọ̀rọ̀, Garba Sheu Àerẹ rọ àwọn àráàlu paapaa àwọn ọ̀dọ́, láti dẹ̀hìn nídi ìwà yóòwu tóòlè dáà rúgúdù sílẹ̀, irúfẹ́ èyí tóò wáyé lákokò ìfẹ̀húnúhàn àipẹ́ yíì.

 Àarẹ Buhari sài tún fọwọ́ ìlérí rẹ̀, sọ̀yà, láti mú òsìsẹ́ ọlọ́pa yóòwù táje ìwà ìbájẹ́ bá símọ́ lórí, fún ìwà ìfipá múni yo kojú ìjìyà tóò yẹ tófimọ́ àwọn tó ńjí ohun ìní ìjọba gbé.

 Lórí ọ̀rọ̀ àrùn covid-19, Àarẹ Buhari tọ́kasi pé orílẹ̀èdè yíì ti se àseyọ́rí láti mójútó ìpèníjà náà pẹ̀lú bí àkọsílẹ̀ àarùn náà se ń fojojúmọ́ dínkù.

Afónja

Yoruba

  Àarẹ Muhammadu Buhari ti sèkìlọ̀ fáwọn ọ̀bàyéjẹ́ tí wọ́n gọ sábẹ́ ìfẹ̀hónúhàn EndSars fidá wàhálà sílẹ̀ lórílẹ̀èdè yíì láti tọwọ́ ọmọ wọn bọsọ.

  Àarẹ ẹnitó sọ èyí nígbà tó ńbá àwọn èèyàn orílẹ̀èdè yíì sọ̀rọ̀, rọ́ọ̀ àwọn ọ̀dọ́ láti sẹ́wẹ́lé ìyansẹ́lódì tí wọ́n gùnlé.

  Ó wá késí àwọn èèyàn ilẹ̀ yíì láti máà báà kárà-kátà wọn lọ, tó sì gbàwọ́n òsìsẹ́ elétò àbò níyànjú láti mú àbò ẹ̀mí àti dúkia àwọn èèyàn ilẹ̀ yíì lọ́kunkúdùn.

 Àarẹ Buhari rọ àwọn èyàn ilẹ̀ yíì láti máà wádi ohun gbogbo dájú-dájú kíwọ́n tóò gbé ìgbésẹ̀.

 Bákanà ló tún ní óba òhun lọ́kàn jẹ́ wípé ìdáhun ojú-ọjọ́ ìsèjọba rẹ̀, láti túù ikọ̀ Sars káà, làwọn kan ríì bí èyí tíkóò dára tóò.

Idogbe