Àarẹ Muhamadu Buhari ti pàsẹ fáwọn àjọ aláàbo nílẹ̀yí láti tẹ̀síwájú lórí gbígbógun ti àwọn ẹni láàbi tó ń pagidínà ètò àbò títí tọ́rọ̀ náà yóò fi dafi seyi tẹ́ẹ̀gun alarẹ fisọ.

Àarẹ sọ̀rọ̀ náà nílu Abuja lásìkò àbẹ̀wò àwọn olórí ilé isẹ́ èètò àbò sí lórí ibi tí ń kan dé dúró, àti àwọn àdojúkọ wọn fún isẹ́ ètò ààbò, papajùlọ lápá ìwọ̀-oorun àríwá àti àrin gbùngbùn àríwá nílẹ̀yí.

Nígbà tón bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdè náà, alákoso fétò àbò, ọ̀gágunfẹ̀yìntì Bashir Magashi sàlàyé pé ọ̀rọ̀ àwọn agbébọn ti di ailesọ lọrun páàka tótó àpérò fọ́mọ eriwo.

Alákoso ọ̀hún ní ìjọba si dúró lórí ipò rẹ̀, pẹ̀lú àlàyé pé ọ̀rọ̀ wíwójùtú sètò àbò jẹ́ ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ fúnjọba, àmọ́sá àgbájọwá táà fi sọ̀yà nikan lọ́nà àbáyọ nílẹ̀yí káláàfìa le jọba.

Ẹwẹ nínú ọ̀rọ̀ rẹ níbi ìpàdé náà, ọ̀gá àgbà ọlọ́pa yányán nílẹ̀yí Alhaji Usman Baba sàlàyé pé gbogbo ikọ̀ aláàbo nílẹ̀yí, yóò fimọ sọ́kan láti fikun akitiyan wọn, tó sèpèjúwe gẹ́gẹ́bí èyí tó ti n kẹ́sẹjárí.

Ayọade/Ọlaọpa

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *