Yoruba

Àrẹ Muhammadu Buhari sọpé ìsèjọba rẹ̀ yo tẹ̀síwájú nínú síse isẹ́ to kí ilẹ̀ Nàijírìa wà ní ìsọ̀kan, kétò ọrọ̀ ajé rẹ̀ si tún dúró digbí tó sì tún jẹ́jẹ láti gbéná wojú àwọn tón domi àlàfìa ìlú rú.

Àrẹ Buhari sọ̀rọ̀ yí lásìkò tón gba àwọn asojú ìgbìmọ̀ àgbàgbà láti ìpínlẹ̀ Borno àti Yobe lálejò nílé àrẹ nílu Abuja.

Àrẹ sọpé wíwà ní ìsọ̀kan tíjọba àpapọ̀ yo si tẹ̀síwájú láti sisẹ́ tọ́ọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, ọ̀jọ̀gbọ́n Babagana Zulum, sọpé àwọn asájú yi ló wá nílu Abuja láti jẹ́ kí àrẹ Buhari mọ àwọn ìpèníjà tí wọ́n ńdojú kọ lẹ́kùn wọn.

Fadahunsi/Afọnja

Yoruba

Àrẹ Muhammadu Buhari ti rọ àwọn asájú nílẹ̀ adúláwọ̀ láti mú àgbéga bá sísàmúlò, mímú òdinwọ̀n bá lílò ìjagun olóró, kí ìsọ̀kan àti àláfìa le débá ètò àbò láwùjọ lápapọ̀.

Àrẹ Buhari sọ̀rọ̀ yí lásìkò ìpàdé pàtàkì ẹlẹkẹrinla, ilẹ adúláwọ̀ ni mímú àgbéga bá àláfìa, ètò àbò, ìsọ̀kan, àti mímúkí rògbòdìyàn dópin nílẹ̀ adúlọ́wọ̀, pẹ̀lú bí wọ́n ti sen kojú ìdúkokò mọ́ni lórí ìgbésùmọ̀mí àtàwọn ìwà ọ̀daràn min.

Óní pẹ̀lú bí ìfẹnukò lórí àláfìa se tín pọsi, Àrẹ pè fún kóríyá lórí ìbásepọ̀ láàrin ọ̀kanòjọ̀kan ẹkun papa lórí ètò ọrọ̀ ajé.

Ajibikẹ/Afọnja