Àrẹ Muhammadu Buhari sọpé ìsèjọba rẹ̀ yo tẹ̀síwájú nínú síse isẹ́ to kí ilẹ̀ Nàijírìa wà ní ìsọ̀kan, kétò ọrọ̀ ajé rẹ̀ si tún dúró digbí tó sì tún jẹ́jẹ láti gbéná wojú àwọn tón domi àlàfìa ìlú rú.

Àrẹ Buhari sọ̀rọ̀ yí lásìkò tón gba àwọn asojú ìgbìmọ̀ àgbàgbà láti ìpínlẹ̀ Borno àti Yobe lálejò nílé àrẹ nílu Abuja.

Àrẹ sọpé wíwà ní ìsọ̀kan tíjọba àpapọ̀ yo si tẹ̀síwájú láti sisẹ́ tọ́ọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, ọ̀jọ̀gbọ́n Babagana Zulum, sọpé àwọn asájú yi ló wá nílu Abuja láti jẹ́ kí àrẹ Buhari mọ àwọn ìpèníjà tí wọ́n ńdojú kọ lẹ́kùn wọn.

Fadahunsi/Afọnja

pub-5160901092443552

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *