Yoruba

Gomina ipinle Oyo, Onimo Ero Seyi Makinde ti salaye igbiyanju eto isakoso ijoba re lori ati koju ipenija eto aabo nipinle naa.

Gomina Makinde se adayanri oro yi lasiko to n gbalejo asoju awon logaloga ileese olodun to lo fun eto idanileko eleekerinlelogoji ile eko oloogun to wa ni Jaji labe akoso asaaju iko naa, eni tii se ogagun ofurufun Air Vice Marshal Ebenezer Alade.

Nigba to n soro lori akori idanileko won naa ti se mimu idagbasoke ba eto aabo nipase igbiyanju nidi eto amulundun ati oro aje, Gomina Makinde salaye wi pe ijoba re ti ro awon odo lagbara, pelu kikowon kuro loju popo leyi to ti mu ki iwa odaran dinku nipinle Oyo, bee lo tun soo di mimo pe ijoba re, ti pese ina sawon oju popo leyi to mu ki igboro maa wa ni imole lalaale.

Saaju ni oludari iko naa, Air Vice Marshal Ebenezer Alade ti soo di mimo pe won ti yan ipinle Oyo, ninu awon ipinle mejo lorileede yi fun ibi ti abewo lori idanilejo naa yii ti maa waye.

Ayodele Olaopa 

Yoruba

Ileese olopa ile yi ti tepele mo igbiyanju lori ipese aabo to peye fawon ileese ati olori jori ton se amulo opopona marose Ibadan silu Eko.

Igbakeji oga agba ileese, Olopa ile yi fun ekun keji, Ogbeni Johnson Kokumo lo fowo oro yi soya nilu Abeokuta lasiko abewo lenu ise to se si Gomina ipinle Ogun, omooba Dapo Abiodun.

Ogbeni Kokumo salaye wi pe ekun keji ileese olopa ile yi lo n se kokari ipinle Ogun ati ipinlle Eko leyi to je ki won maa gbero eto igbogun tiwa odaran alajumo se, Pataki julo lagbegbe Kara lopopona marose.

Nigba to n femi imoore han sijoba to wa lode nipinle Ogun fun ipese inkan iranwo fun leese olopa, Ogbeni Kokumo salaye wipe ileese re ti pari eto gbogbo nidi ati mu eto aabo gbopon lagbegbe naa.

Ninu oro re, Gomina Dapo Abiodun salaye wi pe ileese Oloogun naa ti seleri atileyin fun joba ohun nidi atimaa dode awon ajinigbe, o war o ileese olopa pe ki won se ise po pelu ideese oloogun lati se aseyori.

Babatunde Salaudeen

Yoruba

Àrẹ Muhammade Buhari ti sọ pé àmúgbòrò yo de bá ìgbáyé gbádùn àwọn èyàn nílẹ̀ Nàijírìa, bẹ̀rẹ̀ nípa ìpèsè ètò àbò tó múnádóko.

Nílu Maiduguri, l’afin Shehu ti Borno, ni àrẹ ti sọ̀rọ̀ ìdánilójú yi .

Àrẹ ẹni tó ń se àbẹ̀wò ẹnu isẹ́ ọlọ́jọ́ kan sípinlẹ̀ Borno, ló ti kọ́kọ́ se ìpàdé pọ̀ pẹ̀lú okọ̀ ológun tó wà lágbègbè ọ̀hún.

Óní ìpinu òun láti sin àwọn èyàn orílẹ̀èdè yí, ló wà tatara ifẹ̀ tí wọ́n fihàn sí, bẹ lótún gbóríyìn fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno lórí akitiyan rẹ̀ láti mú ìdàgbàsókè bá ìpínlẹ̀ náà láiwo ìpèníjà lórí àbò tí wọ́n ńlà kọjá.

Nínú ọ̀rọ̀ Shehu tílù Borno, àlhájì Abubakar El-kanemi, dúpẹ́ lọ́wọ́ àrẹ lórí idahun sí ìbere àwọn èyàn ìpínlẹ̀ náà, pẹ̀lú àtọ́kasí pé ètò àbò tin rẹsẹ̀ walẹ̀ sí nípinlẹ̀ ọ̀hún.

Ọlọlade Afọnja