Yoruba

Ipinle Oyo Tenumo Ipese Eto Aabo To Pegede

Gomina ipinle Oyo, Onimo Ero Seyi Makinde ti salaye igbiyanju eto isakoso ijoba re lori ati koju ipenija eto aabo nipinle naa.

Gomina Makinde se adayanri oro yi lasiko to n gbalejo asoju awon logaloga ileese olodun to lo fun eto idanileko eleekerinlelogoji ile eko oloogun to wa ni Jaji labe akoso asaaju iko naa, eni tii se ogagun ofurufun Air Vice Marshal Ebenezer Alade.

Nigba to n soro lori akori idanileko won naa ti se mimu idagbasoke ba eto aabo nipase igbiyanju nidi eto amulundun ati oro aje, Gomina Makinde salaye wi pe ijoba re ti ro awon odo lagbara, pelu kikowon kuro loju popo leyi to ti mu ki iwa odaran dinku nipinle Oyo, bee lo tun soo di mimo pe ijoba re, ti pese ina sawon oju popo leyi to mu ki igboro maa wa ni imole lalaale.

Saaju ni oludari iko naa, Air Vice Marshal Ebenezer Alade ti soo di mimo pe won ti yan ipinle Oyo, ninu awon ipinle mejo lorileede yi fun ibi ti abewo lori idanilejo naa yii ti maa waye.

Ayodele Olaopa 

Related Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *